- f Ọlọrun wa Ọrun,
T’ o fi ọjọ mẹfa
Da nkan gbogbo ti mbẹ laiye
Simi n’ ọjọ keje.
- f O paṣẹ k’a bọ̀wọ
Fun ọjọ isimi;
Ibinu Rẹ̀ tobi pupọ
S’ awọn t’ o rufin yi.
- Awọn baba nla wa,
p Ti kù nin’ okunkun;
Nwọn jẹ ògbó abọriṣa
Nwọn kò mọ̀ ofin Rẹ.
- mf Awa de Oluwa,
Gẹgẹ bi aṣẹ Rẹ;
Lẹhin iṣẹ ijọ mẹfa,
Lati ṣe ifẹ Re.
- mf Mimọ̀ l’ ọjọ oni,
O yẹ ki a simi,
K’ a pejọ ninu ile Rẹ,
K’ a gbọ ‘rọ mimọ Rẹ.
- Isimi nla kan kù
F’ awọn enia Re;
Ọm’ Ọlorun, Alabukun
Mu wa de ‘simi Rẹ ! Amin