- mf Kini ‘Simi ayọ ailopin nì,
T’ awọn angẹl at’ awọn mimọ ni?
mp ‘Simi f’ alarẹ̀; f’ awọn asẹgun,
f Nibẹ l’ Ọlọrun jẹ ohun gbogbo.
- mf ‘Tal’ Ọba na? tani yi ‘tẹ Rẹ̀ ka?
p Irọra itura Rẹ ha ti ri?
mf Sọ funni, ẹnyin ti njọsin nibẹ;
Sọ funni, b’ ọrọ to t’ ayọ nyin so.
- Jerusalem totọ, ilu mimọ,
Alafia eyit’ o jẹ kik’ ayọ;
A r’ ohun t’a nfẹ n’nu rẹ k’a to wi,
A si rigbà jù eyit’ a nfẹ lọ.
- L’ agbala Ọba wa, wahala tán,
Laibẹ̀ru l’a o ma kọrin Sion,
Oluwa, niwaju Rẹ lao ma fi
Idahun ‘fẹ hàn f’ẹbun Ifẹ Rẹ.
- cr ‘Simi kò le tẹle ‘Simi nibẹ;
Ẹnikan ni ‘Simi ti nwoju Rẹ.
f Nibẹ orin jubeli kò le tan,
mp T’ awọn mimọ at’ angẹli y’o kọ.
- cr L’ aiye yi, pẹlu ‘gbagbọ at’ adua,
L’ ao ma ṣafẹri ‘le Baba ọ̀hun;
f Si Salem l’awọn ti a ṣi nipo
mp Npada lọ; --- lat’ ilu Babiloni.
- p Njẹ awa tẹriba niwaju Rẹ,
cr T’ Ẹniti ohun gbogbo jasi;
mf Ninu eniti Baba at’Ọmọ,
T’ Ẹniti Ẹmi jẹ́ Ọkanso lai. Amin.
-