- mf Oluwa wa ọrun!
Agọ Rẹ laiye yi,
Ibugbe ifẹ Rẹ,
Ẹwà rẹ̀ ti pọ̀ to!
ff Ọkàn mi nfà
Lati goke
S’ ibugbe Rẹ,
Ọlọrun mi.
- mf Ayọ̀ b’awọn ti nsìn,
Nibit’ Ọlọrun yàn;
Ti nwọn npara ibẹ,
Lati má jọsin wọn;
ff Nwọn nyin Ọ ṣa:
Ayọ̀ b’ awọn
T’ o fẹ ọna
Oke Sion.
- f Lati ipá de ‘pá
Laiye òṣi wa yi:
Titi nwọn fi goke,
Ti nwọn si yọ ọ’ọrun:
ff ‘Bugbe ogo!
‘Gbat’ Ọlọrun
Ba m’ ẹsẹ wa
De ibẹ̀ ná.
- mf Ọlọrun l’ asa wa,
Imọlẹ at’ odi;
Ọwọ rẹ̀ kún f’ ẹ̀bun,
A ngbà ‘bukun nibẹ:
ff Ayọ̀ pupọ
Ni fun awọn
T’o gbẹkẹle
Ọlọrun wa. Amin.