f ‘Bugbe Rẹ ti l’ẹwa to! N’ ilẹ ‘mọlẹ at’ ifẹ; Bugbe Re ti l’ẹwa to! Laiye ẹṣẹ ati’ òṣì, Ọkan mi nfà nitotọ Fun idapọ̀ enia Rẹ, Fun imọlẹ oju Rẹ, Fun ẹ̀kún Rẹ, Ọlọrun.
f Ayọ̀ ba awọn ẹiyẹ, Ti nfò yi pẹpẹ Rẹ ka; Ayọ̀ ọkàn t’o simi L’aiya Baba l’o pọju! Gẹgẹ b’adaba Noa, Ti ko r’ibi simi le, Nwọn pada sọdọ Baba, Nwọn sì nyọ̀ titi aiye.
f Nwọn kò simi iyìn wọn, Ninu aiye oṣi yi; Omi nsun ni aginju, Manna nt’ọrun wa fun wọn; Nwọn nlọ lat’ ipa de ‘pa, Titi nwọn fi yọ si Ọ; Nwọn si wolẹ l’ẹsẹ Rẹ, T’ o mu wọn là ewu já.
mf Baba, jẹ ki njère bẹ, cr Ṣ’amọna mi laiye yi; F’ ore-ọfẹ pa mi mọ. Fun mi l’àye lọdọ Rẹ: Iwọ l’ Orùn at’ Asà, Tọ́ ọkàn ìṣina mi; Iwọ l’ Orisun ore, Rọ̀ òjo rẹ̀ sori mi.