Hymn 236: Hosanna to the living Lord!

Hossana si Oluwa wa

  1. f Hosanna si Oluwa wa !
    Hosanna si Jesu Ọba !
    Si Ẹlẹda, Olugbala,
    K’aiye, k’ọrun kọ Hosanna;
    ff Kọ Hosanna: “Hosanna loke ọrun.”

  2. Hosanna l’orin Angẹli,
    Hosanna l’orin ti a ngbè;
    L’oke, nisalẹ, yi wa ka,
    Oku at’ ayè ngbè ‘rin na:
    ff Kọ Hosanna: “Hosanna loke ọrun.”

  3. Olugbala ti ntọju wa,
    Pada wa ‘le adurà yi;
    A pejọ ni orukọ Rẹ,
    Mu ileri Rẹ ṣẹ si wa:
    ff Kọ Hosanna: “Hosanna loke ọrun.”

  4. Ṣugbọn, bori ohun gbogbo,
    Fi Ẹmi Rẹ kún ọkàn wa,
    Ki ọkàn wa jẹ ibugbe
    Mimọ ati yiyẹ fun Ọ:
    ff Kọ Hosanna: “Hosanna loke ọrun.”

  5. p L’ọjọ k’ẹhìn, ọjọ ẹ̀ru,
    T’ aiye on ọrun o kọja,
    cr Awọn ti a ti rapada,
    Y’o tun gbè orin iyin na:
    ff Kọ Hosanna: “Hosanna loke ọrun.” Amin