- APA I
f Ọjọ ‘mọlẹ l’eyi:
mf Ki ‘mọlẹ wà l’oni;
cr ‘Wọ Orun, ràn s’okùnkùn wa,
K’ o si le oru lọ.
- p Ọjọ ‘simi l’eyi;
mf S’ agbara wa d’ọtun;
di S’ori aibalẹ aiya wa,
mp Sẹ̀ri itura Rẹ.
- p Ọjọ alafia:
mf F’ alafia funwa;
cr Dá iyapa gbogbo duro,
Si mu ija kuro.
- p Ọjọ adurà ni :
mf K’ aiye sunmọ Ọrun;
cr Gbọkàn wa soke sọdọ Rẹ,
Si pade wa nihin.
- f Ọba ọjọ l’eyi:
mf Fun wa ni isọji;
ff Ji oku ọkàn wa s’ifẹ,
‘Wọ aṣẹgun iku. Amin.
APA II- f Kabọ ! ọjọ ‘simi,
T’o r’ ajinde Jesu;
Ma bọ̀ wá m’ọkàn yi sọji,
Si mu inu mi dùn.
- mf Ọba tikarẹ̀ wá
Bọ́ Ijọ Rẹ̀ loni;
cr Nihinyi l’a wa t’a si ri
A nyin, a ngbadurà.
- mf Ọjọ kan f’ adurà
N’nu ile mimọ Rẹ,
O sàn j’ ẹgbẹrun ọjọ lọ
T’a lò f’ adùn ẹ̀ṣẹ.
- p Ọkàn mi y’o f’ayọ̀
Wà n’ iru ipò yi;
cr Y’o sì ma duro de ọjọ
Ibukun ailopin. Amin.