- mf Mo wi fun olukuluku
f Pe, On ji, O si yè;
O si wà larin wa pẹlu,
Nipa Ẹmi iyè.
- Ẹ wi fun ẹnikeji nyin,
Ki nwọn ji pẹlu wa,
K’ imọlẹ k’ o wà kakiri
Ni gbogbo aiye wa.
- Nisisiyi aiye yi ri
Bi ile Baba wa:
Iyè titun ti On fun ni,
O sọ d’ ile Baba.
- mf Ọna okùn ti On ti rin
Mu ni lọ si ọrun;
Ẹnit’ o rìn bi On ti rìn,
Y’o d’ ọdọ Rẹ̀ l’ọrun.
- f On yè, O si wà pẹlu wa,
Ni gbogbo aiye yi;
Ati nigba’ a f’ ara wa,
F’ erupẹ ni ‘reti. Amin.