- p Jesu ọrẹ ẹlẹṣẹ kú,
Awọn ọmọ Salem nsọkun:
Okunkun bo oju ọrun,
Iṣẹlẹ nla ṣẹ̀ lojiji.
- Nihin l’ a r’ anu ar’ ifẹ,
p Ọba ogo kú f’ enia;
Wo! ayọ̀ ki l’ a tun ri yi,
Jesu t’ O kú tun ji dide.
- f Má bẹ̀ru mọ, ẹnyin mimọ́;
Sọ bi Oluwa ti jọba;
Kọrin b’ O ti ṣẹgun Eṣu,
f Bi O si ti bori ikú.
- ff Ẹ wipe, “Ọba, wà titi,
Iwọ t’ a bi lati gbà wa;”
K’ ẹ bi ikú pe, “Oró rẹ dá?”
“Iboji, iṣẹgun rẹ dà?” Amin.