- f A mu ileri ṣẹ,
Iṣẹ ‘gbala pari:
Otọ at’ anu di ọrẹ́,
Ọm’ Ọlọrun jinde.
- f Ọkàn mi, yin Jesu,
T’ O rù gbogb’ ẹ̀ṣẹ rẹ,
p T’ O kú f’ẹ̀ṣẹ gbogbo aiye;
cr O wà, k’ O ma kú mọ.
- mp Ikú Rẹ̀ ra ‘simi;
Fun ọ, l’ O ji dide;
ff Gbagbọ, gba ẹkún ‘dariji,
T’ a sà l’ àmi ẹjẹ. Amin.