- ff B’ ẹlẹṣẹ s’ ọwọ po,
Ti nwọn nde s’Oluwa,
Dimọ si Kristi Rẹ̀,
Lati gan Ọba na,
B’ aiya ṣata,
Pẹlu Eṣu,
Eke ni nwọn,
Nwọn nṣe lasan.
- f Olugbala jọba !
Lori oke Sion;
Aṣẹ ti Oluwa
ff Gbe Ọmọ Tirẹ̀ ro:
Lati boji
O ni, k’ O nde,
K’ O si goke,
K’ O gba ni là.
- mf F’ ẹru sìn Oluwa,
Si bọwọ f’ aṣẹ Rẹ̀;
F’ ayọ̀ wá sọdọ Rẹ̀,
F’ iwariri duro;
p Ẹ kunlẹ fun,
K’ ẹ tẹriba;
Sọ t’ ipa Rẹ̀,
Ki Ọmọ na. Amin.