- mf Oluwa, ọjọ t’o fun wa pin
Okunkun si de l’ aṣẹ Rẹ;
‘Wọ l’a kọrin owurọ wa si,
Iyìn Rẹ y’o m’alẹ wa dùn.
- mf A dupẹ ti Ijọ Rẹ kò nsùn,
B’ aiye ti nyi lọ s’ imọlẹ,
O sì nṣọonà ni gbogbo aiye,
Kò si simi tọsan-toru.
- B’ ilẹ si ti nmọ lojojumọ
Ni orilẹ at’ ekùsu,
Ohùn adura kò dakẹ ri,
Bẹ l’orin iyin kò dẹkun.
- Orùn t’o wọ̀ fun wa, si ti là
S’ awon ẹda iwọ-orùn,
Nigbakugba li ẹnu sì nsọ
Iṣẹ ‘yanu Rẹ di mimọ̀.
- cr Bẹ, Oluwa, lai n’ ijọba Re,
Kò dabi ijọba aiye:
f O duro, o si nṣe akoso
Tit’ ẹda Rẹ o juba Rẹ. Amin.