f Halleluya, Halleluya, Ẹ gbe ohun ayọ ga, Ẹ kọ orin inudidun, K’ẹ si yiǹ Ọlọrun wa! p Ẹnit’a kàn m’agbelebu, T’o jiya fun ẹṣẹ wa; ff Jesu Kristi Ọba ogo Jinde kuro n’nu oku.
f Irin idabu ṣẹ́ kuro, Kristi ku o si tun yè, O mu iye ati aiku Wa l’orọ ajinde Rẹ̀. Krist ti ṣẹgun, awa ṣẹgun Nipa agbara nla Rẹ̀, ff Awa o jinde pẹlu Rẹ̀, A o ba wọ’nu Ogo.
mf Kristi jinde, akọbi ni Ninu awọn t’o ti sùn Awọn yi ni y’o ji dide, Ni abọ Rẹ̀ ekeji; Ikore ti wọn ti pọ́n tan, Nwọn nreti Olukore, Ẹniti y’o mu wọn kuro, Ninu isa oku wọn.
mf Awa jinde pẹlu Kristi, To nfun wa l’ohun gbogbo, Ojò, ìrì, ati ogo To ntàn jade loju Rẹ̀. Oluwa, b’ a ti wá l’aiye, Fà ọkàn wa sọdọ Rẹ, cr K’ awọn angẹli ṣa wa jọ, Ki nwọn kó wa d’ọdọ Rẹ.
ff Halleluya, Halleluya ! Ogo ni fun Ọlọrun; Halleluya f’ Olugbala, Ẹnit’ o ṣẹgun iku; Halleluya f’ Ẹmi Mimọ, Orisun ‘fẹ, ‘wa mimọ, Halleluya, Halleluya, F’ Ọlọrun Metalọkan. Amin.