- f “Oluwa ji lotọ,”
Ihin na ha ṣ’ otọ?
p Nwọn ti ri p’Olugbala kú,
cr Nwọn ri l’ aye pẹlu.
- f “Oluwa ji lotọ,”
Otọ kò fẹ ju yi;
Anu at’ otitọ pade,
Ti nwọn ti nṣ’ọta ri.
- “Oluwa ji lotọ,”
Iṣẹ Rẹ̀ l’o ṣetan;
f A da ìde onigbọwọ,
A ṣẹ apa ikú.
- “Oluwa ji lotọ,”
mf Boji kò le se mọ;
Awọn t’ o kú si ji pẹlu,
cr Nwọn kì o sì kú mọ. Amin.