- f Krist, Oluwa ji loni, Halleluya.
Ẹda at’ Angẹli nwi – Hal.
cr Gb’ ayọ̀ at` iṣẹgun ga – Hal.
ff K’ ọrun at’ aiye gberin ! – Hal.
- mf Iṣẹe ti idande tan; Hal.
O jija, o ti ṣẹgun; Hal.
Wo, ṣiṣu orùn kọja ---Hal.
cr Kò wọ̀ sinu ẹ̀jẹ mọ ---Hal.
- mf Lasan n’iṣọ at’ ami, Hal
f Krist wó ọrun apada; Hal.
Lasan l’ agbara ikú --- Hal.
Kristi ṣi Paradise. Hal.
- f O tun wà, Ọba ogo: Hal.
“Ikú, itani rẹ wà?” Hal.
p Lẹkan l’ o kú, k’o gba wa. Hal.
cr “Boji, iṣẹgun rẹ wà?” Hal.
- f Ẹ jẹ k’awa goke lọ, --- Hal.
Sọdọ Kristi Ori wa; --- Hal.
A sa jinde pẹlu Rẹ̀ --- Hal.
cr Bi a ti ku pẹluẹ Rẹ̀, --- Hal.
- ff Oluwa t’ aiye t’ ọrun, --- Hal.
Tirẹ ni gbogbo iyìn; --- Hal.
A wolẹ niwaju Rẹ, --- Hal.
‘Wọ Ajinde at’ Iye. Hal. Amin.