Ji, ji, ọkàn ayọ, ji, ji, Oluwa rẹ jinde: Lọ boji Rẹ̀, k’o si mura Ọkan ati kọrin: Gbogbo ẹda l’o si ti ji, Ti nwọn nkọrin didun, Itanna ‘kini t’o kọ tàn Lẹba odo lo hù.
mf Iṣudẹdẹ aiye y’o lọ L’ ọjọ ajinde yi, Iku kò sì mọ n’nu Kristi, Iboji kò n’ ipa; f Ninu Kristi l’a nwà, t’a nsùn, T’a nji, t’a si ndide, p Omije t’iku mu ba wa cr Ni Jesu y’o nù nù.
f Ki gbogb’ ẹiyẹ ati igi At’ itanna ti ntàn, Ki nwọn sọ ti iṣẹgun Rẹ̀, Ati t’ajinde Rẹ̀. Pápá, ẹ gbohun nyin soke, Ẹ bu s’orin ayọ? Ẹnyin oke, ẹ si gberin Wipe, ‘ Iku ti ku.’
ff Ọkan ayọ, ẹ ji, ẹ wa Oluwa t’o jinde; Ẹ yọ ninu ajinde Rẹ̀, K’ọrọ Rẹ̀ tù nyin n’nu, Ẹ gbohun nyin soke, k’ẹ yin Ẹnit’ o ji dide; L’ohùn kan ni ka gberin pe, “Jesu jinde fun mi”. Amin.