f “Kabọ̀, ọjọ rere,” l’ao ma wi titi; A ṣẹtẹ ‘ku loni, Ọrun di ti wa. “Wọ Okú d’ alayè, Ọba tit’ aiye ! Gbogb’ ẹda Rẹ Jesu, ni nwọn njuba Rẹ. ff “Kabọ̀, ọjọ rere,” lao ma wi titi; A ṣẹtẹ ‘ku loni, ọrun di ti wa.
mf Ẹlẹda, Oluwa, Ẹmi alayè ! Lat’ ọrun l’ o ti bojuwo ‘ṣina wa, Ọm’ Ọlọrun papa ni ‘Wọ tilẹ ṣe, K’ O ba lè gbà wa là, O di enia. ff “Kabọ̀, ọjọ rere,” &c.
“Wọ Oluwa iye, O wa tọ ‘ku wò; Lati f’ ipa Rẹ hàn, O sùn n’ iboji; Wa, Ẹni Olotọ, si m’ ọ̀rọ Rẹ ṣẹ, Ọjọ kẹta Rẹ de, jìnde Oluwa ! ff “Kabọ̀, ọjọ rere,” &c.
mf Tu igbekun silẹ, t’ Eṣu dè l’ẹwọn, Awọn t’o si ṣubu, jọ gbe wọn dide; F’ojurere Rẹ hàn, jẹ k’aiye riran, Tun mu ‘mọlẹ wa de, ‘Wọ sá ni ‘mọlẹ; ff “Kabọ̀, ọjọ rere,” lao ma wi titi; A ṣẹtẹ ‘ku loni, ọrun di ti wa. Amin.