- Oluwa ji lotọ,
Olugbala dide,
O f’agbara Rẹ̀ hàn.
L’ or’ ọrun apadi:
N’iberu nla; awọn ẹ̀ṣọ́
Ṣubu lulẹ, nwọn si daku.
- Wo, ẹgbẹ angẹli
Pade l’ ajọ kikun;
Lati gbọ aṣẹ Rẹ̀,
Ati lati juba:
Nwọn f’ ayọ̀ wá, nwọn si nfò lọ,
Lati ọrun si boji na.
- Nwọn tun fò lọ s’ ọrun,
Nwọn mu ‘hin ayọ̀ lọ;
Gbọ iro orin wọn,
Bi nwọn si ti nfò lọ.
Orin wọn ni, Jesu t’ o kú,
Ti ji dide; o ji loni.
- Ẹnyin t’ a rà pada,
Ẹ gberin ayọ̀ na;
Ran iro rẹ̀ kiri,
Si gbogbo agbaiye.
Ẹ ho f’ayọ. Jesu t’ o kú,
Ti ji dide: ki y’o kú mọ.
- Kabiyesi ! Jesu !
T’ o f’ ẹjẹ Rẹ̀ gbà wa:
Ki iyin Rẹ kalè,
Iwọ t’ o ji dide:
A ba Ọ ji, a si jọba,
Pẹlu Rẹ lai; l’ oke ọrun. Amin.