f Eyi l’ ọjọ ajinde, K’aiye wi kakiri: Irekọja didun ni, T’Ọlọrun Olore ! Lat’ inu iku s’iye, Lat’aiye si ọrun, ff Ni Krist ti mu wa kọja, Pẹl’orin iṣẹgun.
mf Oluwa, wẹ̀ ọkàn wa, K’o’ ba le mọ toto; K’a ba le ri Oluwa N’nu ‘mọlẹ ajinde; cr K’a si f’eti s’ohùn Rẹ̀, Ti ndun “ohùn jẹjẹ, Pe, “Alafia fun nyin.” K’ a nde, k’a si tẹle.
f Ẹnyin ọrun, bù s’ayọ̀, K’aiye bẹrẹ orin; Ki gbogbo aiye yika, Dàpọ lati gberin. Ẹda nla ti wẹwẹ, Ẹ gbohùn nyin soke, ff Tori Kristi ti jinde, Ayọ wa ki y’o pin. Amin.