mf Jesu, bukun wa k’a to lọ: Gbìn ọ̀rọ Rẹ si aìya wa; K’o sì mu k’ ifẹ gbigbona Kun ọkàn ilọwọwọ wa; cr Nigba ìye at’ iku wa, p Jesu, jare, se ‘mọlẹ wa.
mp Ilẹ ti ṣu, orùn ti wọ̀; ‘Wọ sì ti ṣìro ìwa wa; Diẹ n’ iṣẹgun wa loni Iṣubu wa l’o papọju; Nigba ìye ati, &c.
mf Jesu, dariji wa: fun wa L’ ayọ, ati ẹ̀ru mimọ, At’ ọkàn ti kò l’ abàwọn K’a ba le jọ Ọ l’ajọtan: Nigba ìye ati, &c.
Lala dùn, ‘tor’ Iwọ ṣe ri; Aniyàn fẹ́rẹ, O ṣe ri; Mà jẹ k’a gbọ t’ ara nikan K’a má bọ sinu idẹwo. Nigba ìye ati, &c.
mp A mbẹ Ọ f’awon alaini, F’ẹlẹṣẹ̀ at’ awọn t’a fẹ; Jẹ ki anu Rẹ mu wa yọ̀, ‘Wọ Jesu, l’ ohun gbogbo wa Nigba ìye ati, &c.
mf Jesu, bukun wa, - ilẹ su: Tikalarẹ wà ba wa gbe: Angẹl’ rere nṣọ ile wa; A tun f’ ọjọ kan sunmọ Ọ. Nigba ìye ati, &c. Amin.