- f Jesu yè; titi aiye
Ẹru ikú kò bà ni mọ;
Jesu yè; Nitorina
Isa okù kò n’ ipa mọ.
Alleluya !
- mf Jesu yè; lat’ oni lọ,
Ikù jẹ ọ̀na si ìye;
di Eyi y’o jẹ ‘tunú wa,
‘Gbat’ akoko ikú ba de.
Alleluya !
- mp Jesu yè; fun wa l’ o kú,
cr Njẹ Tiré ni a o ma ṣe;
A o f’ ọkan funfun sìn,
A o f’ ogo f’ Olugbala.
Alleluya !
- f Jesu yè; eyi daju,
Iku at’ ipá okunkun
Kì y’o lè yà ni kuro
Ninu ifẹ nla ti Jesu.
Alleluya !
- Jesu yè; gbogbo ‘jọba
L’ ọrun, li aiye, di Tirè;
mf Ẹ jẹ ki a ma tẹ̀le,
cr Ki a lè jọba pẹlu Rẹ̀.
Alleluya ! Amin.