- f Orọ̀ ayọ na de,
Olugbala bori;
cr O fi boji silẹ
Bi Olodumare,
ff A d’ igbekun ni gbekun lọ;
Jesu t’ o kú di alàye.
- p Onigbọwọ wa kú
mf Tani to fi wa sùn?
Baba da wa lare,
Tal’ o to da ẹbi?
ff A d’ igbekun, &c.
- f Kristi ti san gbesè;
Iṣẹ ogo pari;
O ti ràn wa lọwọ;
O ti ba wa ṣẹgun.
ff A d’ igbekun, &c. Amin.