- f L’ owurọ Ọjọ Ajinde,
T’ara t’ọkàn y’o pade,
Ẹkun, ‘kanu on irora
Y’o dopin.
- p Nihin nwọn ko’ le ṣai pinya,
Ki ara ba le simi,
K’ o si fi idakẹrọrọ
Sùn fọnfọn.
- Fun ‘gbà die ara arẹ̀ yi
L’a gbe s’ibi ‘simi rè;
cr Titi di imọlẹ orẹ̀
Ajinde.
- mf Ọkàn t’o kanu nisiyi,
To si ngbadura kikan,
f Y’o bu s’orin ayọ l’ọjọ
Ajinde.
- mf Ara at’ ọkàn y’o dapọ,
Ipinya kò ni si mọ;
cr Nwọn o jí l’aworan Krist, ni
‘Tẹlọrùn.
- f A! ẹwa na at’ ayọ̀ na
Y’o ti pọ̀ to l’ Ajinde!
Y’o duro, b’ọrun at’ aiye
Ba fò lọ.
- mf L’orọ̀ ọjọ ajinde wa,
‘Boji y’o m’ oku rẹ̀ wa;
Baba, iya, ọmọ, ará
Y’o pade.
- Si ‘dapọ ti o dùn bayi,
di Jesu maṣai kà wa yẹ;
p N’nu ‘ku, ‘dajọ, k’a le rọ̀ m’a---
‘Gbelebu. Amin.