- mp Isimi awọn mimọ,
Ọjọ ohun ijinlẹ,
Ti Ẹlẹda ti bukùn,
Apẹrẹ isimi Rẹ̀.
cr Oluwa simi ‘ṣẹ Rẹ̀,
O yà ‘jọ na si mimọ
- p Loni oku Oluwa
Nsimi ninu iboji,
A ti we l’aṣọ oku,
Lat’ ori titi d’ẹsẹ,
A si fi okuta se,
A si fi edidi di.
- mp Oluwa, titi aiye,
L’a o ma pa eyi mọ
A o t’ilẹkun pinpin,
K’ariwo ma ba wọle,
cr A o fi suru duro,
Tit’ Iwọ o tun pada,
- p Gbogbo awọn t’o ti sùn,
Nwọn o wa ba Ọ simi;
Nwọn o bọ lọwọ lala,
cr Nwọn nreti ipè ‘kẹhin,
f T’a o di ẹda titun,
T’ayọ wa ki y’o l’opin.
- mf Jesu yọ wa nin’ ẹṣẹ,
K’a ba le ba wọn wọle,
cr Ewu ati ‘sẹ́ y’o tán,
A o f’ayọ goke lọ,
f A o ri Ọlọrun wa,
A o si ma sin lailai. Amin.