- p Lẹba ibojì Jesu mi,
Nigbat’ òkunkun bò ilẹ,
Awọn aṣọfọ duro jẹ.
- p Ara arẹ̀ jàja simi,
Irora ati wahala
Ẹnit’ o jiya wa pari.
- Ihò t’a wọ̀ n’nu okuta
Ni a – tẹ́ Olugbala si;
Ọlọrun, Ẹlẹda aiye.
- Ẹnyin t’ ọfọ ṣẹ̀, t’ẹ ndarò,
Nihin n’ isimi wà fun nyin;
mp Nihin, k’ ibanujẹ nyin pin. Amin.