“Baba, dariji wọn; nitori ti nwọn kò mọ̀ ohun ti nwọn nṣe.” --- Luk.23,34
- mf ‘Wọ t’o mbẹbẹ f’ ọta Rẹ,
L’ or’ igi agbelebu;
Wipe, “fiji wọn Baba:”
p Jesu, ṣanu fun wa.
- mf Jesu, jọ bẹbẹ fun wa,
Fun ẹ̀ṣẹ wa gbagbogbo;
A kò mọ̀ ohun t’ a nṣe:
p Jesu, ṣanu fun wa.
- Jẹ k’ awa ti nwá anu,
Dabi Rẹ l’ ọkàn n’ iwa,
‘Gbat’ a ba ṣe wa n’ibi:
p Jesu, ṣanu fun wa.
“Loni ni iwọ o wa pẹlu mi ni Paradise” --- Luk. 23,43
- mf Jesu, ‘Wọ t’ o gbọ́ arò
Ole t’ o kú l’ ẹgbẹ́ Rẹ,
T’ o si mu d’ ọrun rere:
p Jesu, ṣanu fun wa.
- mf Ninu ẹbi ẹ̀ṣẹ wa,
Jẹ k’ a tọrọ anu Rẹ,
K’ a ma pe orukọ Rẹ:
p Jesu, ṣanu fun wa.
- mp Ranti awa ti nrahùn,
T’ a nwò agbelebu Rẹ;
F’ ireti mimọ́ fun wa,
p Jesu, ṣanu fun wa.
“Obinrin, wò ọmọ rẹ. Wò iya rẹ.” ---Joh. 19: 26,27
- mf ‘Wọ t’ o fẹ l’ afẹ dopin
Iya Rẹ t’ o nkan Rẹ,
Ati ọrẹ Rẹ ọwọ́n:
p Jesu, ṣanu fun wa.
- mf Jẹ k’ a pin n’nu ìyà Rẹ,
K’ a má kọ ikú fun Ọ,
cr Jẹ k’ a ri tọju Rẹ gba:
p Jesu, ṣanu fun wa.
- f Ki gbogbo awa Tirẹ
Jẹ ọmọ ile kanna;
cr ‘Tori Rẹ, k’ a fẹ ra wa:
p Jesu, ṣanu fun wa.
Ọlọrun mi, Ọlọrun mì eṣe ti iwọ fi kọ mi silẹ̀ --- Matt. 27,46
- mf Jesu, ‘Wọ ti ẹ̀ru mbà,
‘Gbat’ o si kù ‘Wọ nikan,
cr Ti okunkun ṣu bò Ọ:
p Jesu, ṣanu fun wa.
- ‘Gbati a ba npè lasan,
T’ ireti wa si jina;
N’nu okun na di wa mu:
p Jesu, ṣanu fun wa.
- B’ o dabi Baba kò gb´,
B’ o dabi ‘mọlẹ̀ kò si,
Jẹ k’ a f’igbagbọ ri Ọ,
p Jesu, ṣanu fun wa.
“Orungbe ngbe mi.” --- Joh. 19,28
- mf Jesu, ninu ongbẹ Rẹ,
Ni ori agbelebu,
Wọ ti o fẹ wa sibẹ:
p Jesu, ṣanu fun wa.
- mf Ma kongbẹ fun wa sibẹ,
Ṣiṣẹ mimọ́ l’ ara wa;
Tẹ́ ifẹ Rẹ na l’ ọrun;
p Jesu, ṣanu fun wa.
- mf Jẹ k’ a kongbẹ ife Rẹ,
Ma ṣamọna wa titi,
Sibi omi ìye nì;
p Jesu, ṣanu fun wa.
“O pari.” Joh. 19,30
- mf Jesu Olurapada,
‘Wọ t’ ṣe ‘fẹ Baba Rẹ,
T’ o si jiya ‘tori wa;
p Jesu, ṣanu fun wa.
- mf Gba wa l’ ọjọ idamu,
Ṣe oluranlọwọ wa,
Lati ma t’ ọ̀na mimọ́;
p Jesu, ṣanu fun wa.
- mf F’ imọlẹ Rẹ s’ ọna wa,
Ti y’o ma tàn titi lai,
Tit’ ao fi de ọdọ Rẹ:
p Jesu, ṣanu fun wa.
“ Baba, li ọwọ Rẹ ni mo fi ẹmi mi le.” --- Luk 23,46
- mf Jesu, gbogbo iṣẹ Rẹ,
Gbogbo ijamu Rẹ pin;
O jọw’ ẹmi Eẹ lọwọ;
p Jesu, ṣanu fun wa.
- mf ‘Gbat’ ikú ba dé bá wa,
Gbà wa lọwọ ọta wa;
f Yọ wa ni wakati na,
p Jesu, ṣanu fun wa.
- Ki ikú at’ iye Re.
Mu ore-ọfẹ ba wa,
Ti yio mu wa d’ oke;
p Jesu, ṣanu fun wa. Amin.