- mf Olugbala mi ha gbọgbẹ!
Ọba ogo ha ku!
On ha jẹ f’ ara Rẹ̀ rubọ
F’ẹni ilẹ b’emi?
- mp Iha ṣe ẹsẹ ti mo dam
L’o gbe kọ́ s’or’ igi?
cr Anu at’ ore yi ma pọ̀,
Ifẹ yi rekọja!
- mp O ye k’ Orùn f’ oju pamọ,
K’ o b’ogo rẹ̀ mọlẹ́;
Gbati Kristi Ẹlẹda kú,
Fun ẹ̀ṣẹ ẹda Rẹ̀.
- mp Bẹ l’ o yẹ k’ oju ba tì mi,
‘Gba mo r’ agbelebu;
O yẹ k’ ọkàn mi kun f’ọpẹ,
Oju mi f’ omije.
- mf Ṣugbọn omije kò lè san
Gbese ‘fẹ ti mo jẹ;
Mo f’ ara mi f’Oluwa mi,
Eyi ni mo le ṣe. Amin.