- mf Ẹnyin ti kọja,
Yà sọdọ Jesu:
p O ṣ’asan fun nyin bi, pe ki Jesu kú?
- Alafia nyin,
Onigbọwọ nyin:
pp Wá wò bi banujẹ kan ri bayi ri.
- f Oluwa n’ jọ na,
N’ ibinu Rẹ̀ gbe
Ẹṣẹ nyin l’ Ọdagutan, O kó wọn lọ.
- p O kú, k’o ṣ’etù
Nitor’ ẹ̀ṣẹ nyin:
Baba ṣẹ Ọmọ Rẹ̀ n’ iṣẹ́ ‘tori nyin.
- K’ a gb’ ore-ọfẹ
Irapada mu,
Fun ẹni t’ o jiya t’o kú nipò wa.
- Nigb’ aiye ba pin
Awa o ma bọ
ff Ifẹ titobi na, ti ki tan lailai. Amin.