Hymn 21: Savior, breathe an evening blessing

K’ a to sun, Olugba wa

  1. mp K’a to sùn, Olugbala wa,
    Fun wa n’ Ibukun alẹ’
    A jẹwọ ẹ̀ṣẹ wa fun Ọ
    Iwọ l’o le gbà wa la.

  2. cr B’ ilẹ tilẹ ti ṣududu,
    Okùn kò le se wa mo;
    mf Iwọ ẹniti kì ṣarẹ̀
    Nṣọ awọn enia Rẹ.

  3. p B’ iparun tilẹ yi wa ka,
    Ti ọfa nfò wa kọja,
    mf Awọn Angẹli yi wa ka,
    Awa o wà l’ ailewu.

  4. p Ṣugbọn b’ iku ba ji wa pa,
    Ti ‘bùsun wa d’ ibojì,
    mf Jẹ k’ ilẹ mọ wa sọdọ Rẹ
    L’ ayọ at’ Alafia.

  5. p N’ irele awa f’ ara wa
    Sabẹ àbo Rẹ, Baba;
    Jesu, ‘Wo t’o sùn bi awa,
    Ṣe orun wa bi Tirẹ.

  6. Ẹmi Mimọ, r`adọ bò wa,
    Tan imọlẹ s’okùnkun wa
    cr Tit’ awa o fi ri ọjọ
    f Imọlẹ aiyeraiye. Amin