- mf Agbelebu ni ere mi,
Nibẹ ni a rubọ fun mi;
Nibẹ l’ a kàn Oluwa mọ,
Nibe l’Olugbala mi kú.
- mf Kini o lè fa ọkàn Rẹ
Lati tẹri gba ìya mi?
Aimọhun na daju l’ o ṣe
p T’ ọkàn mi tutu bẹ si Ọ.
- mf Aifọhun na oju tì mi
Niwaju Jesu mimọ́ mi,
p T’ o tajẹ̀ Rẹ̀ silè fun mi,
Tori o fẹ mi l’ afẹju. Amin.