- mf ‘Gbati mo ri agbelebu,
Ti a kàn Ọba ogo mọ,
Mo kà gbogbo ọrọ̀ s’ ofo,
Mo kẹgan gbogbo ogo mi.
- cr K’ a ma’ ṣe gbọ pe, mo nhalẹ̀,
B’ o yẹ̀ n’ ikú Oluwa mi;
Gbogbo nkan asan ti mo fẹ,
Mo da silẹ fun ẹ̀jẹ Rẹ̀.
- p Wo lat’ ori, ọwọ, ẹsẹ̀;
B’ ikanu at’ ifẹ ti nṣàn;
cr ‘Banujẹ at’ ifẹ papọ,
A f’ẹ̀gun ṣe ade ogo.
- mf Gbogbo aiye ba jẹ t’ emi,
Ẹbun abẹrẹ ni fun mi;
f Ifẹ nla ti nyanilẹnu
Gba gbogbo ọkàn, ẹmi mi. Amin.