- mf Wakati didun ni fun mi,
p Ni wíwò agbelebu,
cr Nibẹ Jesu fun mi n’ Iye,
‘Lera at’ alafia.
- mp Nihin l’emi o gbe joko
Lati wò isun ẹ̀jẹ,
p Eyiti y’o wẹ ọkàn mi,
K’Ọlọrun ba le gbà mi.
- mf Niwaju agbelebu Rẹ̀,
p L’em’ o ba buruburu,
‘Gbat’ emi ba ri, ‘yọnú nla
T’o farahan loju Rẹ̀.
- Ifẹ ati omije mi,
Ni ngo fi wẹ̀ ẹsẹ Rẹ̀,
cr ‘Tori mo mọ̀ pe iku Rẹ̀
Y’o mu ìye wa fun mi.
- mf Oluwa, jọ gbà ẹ̀bẹ mi,
cr Ṣe ọkàn mi ni Tire,
f Tit’ emi o fi ri ‘gbala,
At’ oju Rẹ n’nu ogo. Amin.