f Ọlọrun fẹ araiye, O fẹ tobẹ gẹ; T’ o ran ọmọ Rẹ̀ w’ aiye, T’ o kù fun ẹ̀lẹṣẹ Ọlọrun ti mọ̀ tẹlẹ̀ p Pe, emi o ṣẹ̀ si Ofin, ati ifẹ Rè, Iwọ ha fẹ mi bi?
Lotọ Ọlọrun fẹ mi, Ani-ani kò si; Awọn t’o yipada si, Igbala ni nwọn ri, pp Wò! Jesu Kristi jiya, Igi l’ a kàn a mọ; Wo! ẹjẹ Rẹ̀ ti o ṣàn, Wo! ro! Má dẹṣẹ mọ.
p Jesu, agbelebu Rẹ ni Ngo kàn ẹ̀ṣẹ mi mó; Labẹ agbelebu Rẹ, Ngo wẹ ẹ̀ṣẹ mi nù, mf Nigbat’ emi o ri Ọ, Ni ọrun rere Rẹ; ff Nki yio dẹkun yin Ọ, F’ ogo at’ ọla Rẹ. Amin.