- mf Wò Ọdagutan ti o rù
Ẹrù rẹ lor’ igi;
O ku lati dá igbekun,
p O t’ẹjẹ Rẹ̀ fun ọ.
- mp W’Olugbala, tit’ iran na
Y’ o fi à ọkàn rẹ;
p Fi omije rin ẹsẹ Rẹ̀,
Má kuro lọdọ Rẹ̀.
- cr Wo, tit’ ifẹ Rẹ̀ yio fi
Jọba lor’ ọkàn rẹ;
Tit’ agbara Rẹ̀ y’ o fi hàn
Lor’ ara on ẹmi.
- mf Wo, b’ iwọ ti nsare ije,
Ọrẹ rẹ titi;
f Y’ o pari ‘ṣẹ Rẹ̀ t’ O bẹrẹ,
Or’ọfẹ y’o j’ogo. Amin.