Hymn 203: Hark! the voice of love and mercy

E gb’ ohun ife at’ anu

  1. mf Ẹ gb’ ohun ifẹ at’ anu,
    Ti ndún l’ oke Kalfari!
    Wo! O san awọn apata!
    O mì ‘lẹ̀, o m’ọrun ọu!
    p “O ti pari,” “O ti pari,”
    Gbọ́ b’ ‘Olugbala ti ke.

  2. mp “O ti pari!” b’o ti dùn to,
    Ohun t’ ọ̀rọ wọnyi wi,
    Ibukun ọrun l’ ainiye
    Ti ọdọ Krist ṣàn si wa;
    p “O ti pari,” “O ti pari”,
    Ẹ ranti ọrọ wọnyi.

  3. f Iṣẹ igbala wa pari,
    Jesu ti mu ofin ṣẹ;
    O pari, nkan t’Ọlọrun wi
    Awa ki o ka ‘ku si;
    p “O ti pari,” “O ti pari”,
    Ẹlẹṣẹ, ìpẹ l’ eyi.

  4. f Ẹ tun harpu nyin ṣe, Seraf,
    Lati kọrin ogo Rẹ̀;
    Ar’ aiye at’ ara ọrun,
    Yin ‘rukọ Emmanuel;
    p “O ti pari,” “O ti pari!”
    Ogo fun Ọd’agutan. Amin.