APA I- p Okùn l’ alẹ, tutù n’ilẹ,
Nibi Kristi wolẹ̀,
p Ogùn Rẹ̀ bi iro ẹjẹ̀,
Ninu ‘wayà ija.
- mf “Baba gb’ ago kikoro yi,
B’ o ba ṣe ifẹ Rẹ;
Bi bẹkọ́, Emi o si mu,
Ifẹ Rẹ ni k’a ṣe.”
- Ẹlẹṣẹ lọ wò l’ agbala,
Ẹjẹ mimọ́ wọnni:
p O r’ ẹrù wuwo ni fun ọ,
O rẹ ‘ra ‘lẹ fun ọ.
- Kọ̀ lati gbe agbelebu,
Ṣe ifẹ ti Baba;
Nigba idanwo sunmọle,
ff Ji, ṣọra, gbadura. Amin.
APA II- p Ki Jesu ha nikan jìya,
K’ araiye lọ lofo?
p Iya mbẹ f’olukuluku;
cr Iyà si mbẹ fun mi.
- p Em’ o rù agbelebu mi,
Tit’ iku y’o gbà mi;
mf ‘Gbana, ngo lọ ‘le lọ d’ ade,
‘Tor’ ade mbẹ fun mi.
- f Nilẹ ita kristali na,
Leba ẹsẹ Jesu,
f Ngo f’ade wura mi lelẹ;
Ngo yin orukọ Rẹ̀.
- f A! agbelebu! A! ade!
cr A! ọjọ ajinde!
Ẹnyin Angẹl, ẹ sọkalẹ,
Wá gbe ọkàn mi lọ. Amin.