- mf Oke kàn mbẹ jìna rèrè
Lẹhìn odi ilu,
p Nibit’ a kàn Oluwa mọ,
cr Ẹnit’ o ku fun wa.
- p A kò le mọ̀, a kò le sọ,
B’ irora Rẹ̀ ti to,
cr Ṣugbọn a mọ̀ pe ‘tori wa
L’O ṣe jìya nibe.
- mf O ku k’a le ri ‘dariji,
K’a le huwa rere:
cr K’a si le d’ọrun nikẹhin,
p N’ itoye ẹjẹ Rẹ̀.
- mf Kò tun s’ẹni ‘re miran mọ,
T’o le sanwo ẹ̀ṣẹ;
On l’o le ṣilẹkun ọrun,
K’o sì gbà wa sile.
- f A! b’ ifẹ Rẹ̀ ti ṣọwọn to,
O yẹ k’a fẹran Rẹ!
K’ a sì gbẹkẹle ẹ̀jẹ Rẹ.
K’ a si ọe ifẹ Rẹ. Amin.