- Ogo ni fun Jesu
p T’o f’ irora nla
cr Ta ẹ̀jẹ Rẹ̀ fun mi
Lati ìha Rẹ̀.
- f Mo r’ ìye ailopin
Ninu ẹjẹ na;
Iyọ́nu Rẹ̀ sa pọ̀,
Ore Rẹ̀ ki tán.
- f Ọpẹ ni titi lai,
F’ẹjẹ ‘yebiye
T’o rà aiye pada,
Kuro n’nu egbe.
- mf Ẹjẹ Abel’ nkigbe
Si ọrun f’ ẹsan;
Ṣugb’ ẹ̀jẹ Jesu nké
f Fun ‘darijì wa.
- p Nigbati a bu wọ́n
Ọkàn ẹ̀ṣẹ wa,
Satan, n’ idamu rẹ̀,
F’ẹru sa jade.
- f Nigbat’ aiye ba nyọ̀,
T’o ngbe ‘yìn Rẹ̀ ga,
Awọn ogun Angẹl
A ma f’ ayọ̀ gbe.
- f Njẹ, ẹ gbohùn nyin ga,
Ki ìró na dún !
ff Kikan lohùn goro,
Yin Ọdagutan. Amin.