mp ‘Wọ Imọlẹ ! larin okun aiye Ma sìn mi lọ. Okunkun ṣù, mo si jina s’ ile; Ma sìn mi lọ. cr Tọ ‘ṣisẹ mi: ohun ẹhin ọla Emi kò bere : ‘ṣisẹ̀ kan to fun mi.
p Nigbakan ri, emi ko bẹ Ọ, pe, Ma sìn mi lọ. Bẹni nkò fẹ Ọ; ṣugbọn nigbayi Ma sìn mi lọ. Afẹ aiye ni mo ti ntọ lẹhin; Ṣugbọn Jesu, má ranti igbani.
mf Ipa Rẹ l’o ti ndi mi mu, y’o si Ma sìn mi lọ. Ninu ẹrẹ̀ ati yangi aiye, Ma sìn mi lọ. Titi em’ o fi ri awọn wọnni Ti mo fẹ, ti nwọn ti f’ aiye silẹ.
K’o to d’igba na, lọna aiye yi T’ iwọ ti rin, Ma sìn mi lọ, Jesu Olugbala S’ile Baba; p Ki nle simi lẹhin ija aiye Ninu imọle ti ko nipẹkun. Amin