- mf Ninu gbogbo ewu oru,
Oluwa l’o ṣọ́ mi;
Awa si tun ri ‘mọlẹ yi
A tun tẹ ekun ba.
- Oluwa, pa wa mo l’ oni,
Fi apa Rẹ ṣọ́ wa;
Kiki awọn ti ‘wọ pamọ’
L’ o nyọ ninu ewu.
- K’ ọ̀rọ wa, ati ìwa wa
Wipe, Tirẹ l’awa;
Tobẹ t’ imọle otitọ
Lè tàn l’ oju aiye.
- Ma jẹ k’ a pada lọdọ Rẹ,
Olugbala ọwọn;
Titi a o f’ oju wa ri
Oju Rẹ li opin. Amin.