- mp Arà, ẹ wa ba mi ṣọfọ;
Ẹ wá sọdọ Olugbala;
Wa, ẹ jẹ k’a jumọ sọ̀fọ;
p A kàn Jesu m’ agbelebu.
- mp Kò ha s’omije loju wa,
Bi awọn Ju ti nfi ṣẹ̀fẹ?
A! ẹ wo, b’ O ti tẹriba;
p A kàn Jesu m’ agbelebu.
- mp Ẹmeje l’ O sọ̀rọ ifẹ;
p Idakẹ wakati mẹta
L’ o fi ntọrọ anu f’ enia;
A kàn Jesu m’ agbelebu.
- cr Bu s’ẹkun, ọkàn lile mi !
mp Ẹṣẹ at’ igberaga rẹ
L’o da Oluwa rẹ l’ẹbi;
p A kàn Jesu m’ agbelebu.
- Wa duro ti agbelebu,
K’ẹ̀jẹ ti njade niha Rẹ̀
Ba le ma ṣàn le ọ lori;
p A kàn Jesu m’ agbelebu.
- cr Ibanujẹ at’ omije,
Bère, a kì o fi dù ọ;
‘Banujẹ l’o nf’ ifẹ rẹ hàn:
p A kàn Jesu m’ agbelebu.
- f Ifẹ Baba, ẹ̀ṣẹ ẹda,
Nihin l’a ri agbara re;
Ifẹ l’o si di Aṣẹgun,
p A kàn Olufẹ wa mọgi. Amin.