Hymn 198: Come let’s unto Jesus attend

E je k’a to Jesu wa lo

  1. mf Ẹ jẹ k’a tọ Jesu wa lọ,
    Ni agbala nla ni;
    Nibiti o nlọ gbadura,
    p Nibit’ o nlọ kanu.

  2. K’a wò b’ O ti dojubolẹ̀,
    p T’ o mmi ìmí ẹdùn;
    Ẹrù ẹ̀sẹ wa l’ O gberù,
    Ẹṣẹ gbogbo aiye.

  3. Ẹlẹṣẹ, wò Oluwa rẹ,
    Eni mimọ́ julọ;
    Nitori rẹ ni Baba kọ,
    Aiye si d’ ọta rẹ̀.

  4. mf Iwọ o ha wo laironu,
    Lai k’ẹ̀ṣẹ rẹ silẹ?
    p Ọjọ idariji nkọja,
    Ọjọ igbala nlọ. Amin.