mp W’Olori Alufa Giga B’o ti gbe ẹ̀bẹ wa lọ; p L’ọgba, o f’ikedùn wolẹ̀, O f’ẹru dojubolẹ; Angẹli f’idamu duro Lati ri Ẹlẹda bẹ; cr Awa o ha wà l’ aigbọgbẹ, T’a mọ̀ pe tori wa ni?
mf Kiki ẹjẹ Jesu nikan L’ o le yi ọkàn pada; On l’o le gbà wa n’nu ẹbi, On l’o ke m’ọkàn wa rò; Ofin at’ ìkilọ kò to, Nwọn kò si le nikan ṣe; cr Ero yi l’o m’ọkàn rò: Oluwa ku dipò mi !
mf Jesu, gbogbo itunu wa, Lat’ ọ̀dọ Rẹ l’o ti nwá; cr Ifẹ, ‘gbagbọ, ‘reti, surù, Gbogbo rẹ̀ l’ẹjẹ Rẹ rà; f Lat’ inu ẹ̀kun Rẹ l’a ngba, A kò da ohun kan ni; Lọfẹ n’ Iwọ nfi wọn tọrẹ Fun awọn t’o ṣ’alaini. Amin.