- f “Hosanna, s’Ọmọ Dafidi:”
ff Hosanna! ẹ kọrin!
“Olubukun l’ẹniti mbọ̀
Lorukọ Oluwa.”
- f “Hosanna s’Ọmọ Dafidi:”
L’ẹgbẹ Angẹli nké;
ff Gbogb’ ẹda, ẹ jùmọ gberin,
Hosanna s’Ọba wa.
- Hosanna ! awọn Heberu
Jà im’ọpẹ s’ọna;
Hosanna ! a mu ẹ̀bun wá
Fi tun ọ̀na Rẹ ṣe.
- ff T’àgba t’ewe nke, Hosanna!
p K’ijiya Rẹ to de;
L’oni, a sì nkọ Hosanna!
B’o ti njọba lokè.
- B’o ti gbà ‘yìn wọn nigbana,
p Jọ, gbà ẹ̀bẹ wa yi!
Lọrun, k’a le b’Angẹl kọrin,
ff Hosanna s’Ọba wa. Amin.