- f Ma gẹṣin lọ l’ọlanla Re;
Gbọ! Gbogb’ aiye nke “Hosanna”;
mp Olugbala, ma lọ pẹlẹ
Lori im’ ọpẹ at’ aṣọ.
- f Ma gẹṣin lọ l’ọlanla Re;
p Ma f’ irẹlẹ gẹṣin lọ ku:
cr Kristi, ‘ṣẹgun Rẹ bẹrẹ na,
Lori ẹṣẹ ati iku.
- f Ma gẹṣin lọ l’ọlanla Re;
di Ogun angẹli lat’ Ọrun
Nf’iyanu pẹlu ikanu
p Wò ẹbọ to sunmọle yi
- f Ma gẹṣin lọ l’ọlanla Re;
mf Ija ikẹhin na de tan;
Baba, lor’ itẹ Rẹ̀ lọrun,
Nreti ayanfẹ Ọmọ Rẹ̀.
- f Ma gẹṣin lọ l’ọlanla Re;
p Ma f’irẹlẹ gẹṣin lọ ku;
pp F’ ara dà irora f’ẹda;
Lẹhìn na, nde, k’o ma jọba. Amin.