- f Gbogb’ ogo, iyin, ọla,
Fun Ọ, Oludande,
S’Ẹni t’ awọn ọmọde
Kọ Hosanna didun!
‘Wọ, l’Ọba Israeli,
Ọm’ Alade Dafid,
T’ O wá l’Okọ Oluwa,
Ọba Olubukun.
Gbogb’ ogo, iyin, ọla,
Fun Ọ, Oludande,
S’ Ẹni t’ awọn ọmọde
Kọ Hosanna didun.
- ff Ẹgbẹ awọn maleka
Nyin Ọ loke giga;
Awa at’ ẹda gbogbo
Si dapọ gberin na.
Gbogb’ ogo, iyin, ọla, &c.
- f Awọn Hebru lọ ṣaju,
Pẹlu imọ ọpẹ;
Iyin, adua, at’ orin,
L’ a mu wá ‘waju Rẹ.
Gbogb’ ogo, iyin, ọla, &c.
- mf Si Ọ ṣaju iyà Rẹ,
Nwọn kọrin iyin wọn;
‘Wọ t’ a gbega nisiyi,
L’ a nkọrin iyin si,
Gbogb’ ogo, iyin, ọla, &c.
- cr ‘Wọ gbà orin iyin wọn:
Gb’ adura t’ a mú wá,
‘Wọ ti nyọ̀ s’ohun rere,
Ọba wa Olore.
Gbogb’ ogo, iyin, ọla, &c. Amin.