- f Tani le sọ t’ayọ̀ ti mbẹ
Ni àgbala Paradise;
p Gbat’ amuṣua ba pada,
T’o si di arole ogo?
- f Ni ayọ̀ ni Baba fi wò
Eso ifẹ Rẹ̀ ailopin:
L’ayò l’Ọmọ wò ‘lẹ, t’o ri
Ere iwaya-ijà Rẹ̀.
- f Tayọtayọ̀ l’Ẹmi si nwò,
Ọkan mimọ t’ On sọ d’ọtun;
Awọn mimọ at’ Angẹl nkọ
ff Orin igbilẹ Ọba wọn. Amin.