- mf Iwọ ẹlẹṣẹ, Ẹmi nfi anu pè
Ọkàn rẹ t’o ti yigbi ninu ẹṣẹ;
Maṣe ba Ẹmi ja, ma pẹ titi mọ,
Ẹbẹ Ọlọrun rẹ le pari loni.
- f Ọmọ Ijọba, má ṣ’ ẹrú ẹṣẹ mọ;
Gb’ ẹ̀bun Ẹmi Mimọ ati itunu:
Má bi Ẹmi ninu, Olukọ rẹ ni, ---
K’a ba le ṣe Olugbala rẹ logo.
- p Tempili d’ ibajẹ, ẹwà rẹ̀ d’ ilẹ;
Ina pẹpẹ Ọlọrun fẹrẹ ku tan,
Bi a fi ifẹ da, O si le tun ràn:
Maṣe pa ‘na Ẹmi, Oluwa mbọ̀ wá. Amin.