f Oluwa mo gbọ pe, Iwọ Nrọ̀ òjo ‘bukun kiri; Itunu fun ọkàn arẹ, Rọ̀ òjo na sori mi--- An’ emi, An’ emi, pp Rọ̀ òjo na sori mi.
mf Má kọja, Baba Olore, Bi ẹ̀ṣẹ mi tilẹ pọ̀; ‘Wọ le fi mi silẹ, ṣugbọn p Jẹ k’anu Rẹ bà le mi --- An’ emi.
mf Má kọja mi, Olugbala, Jẹ k’emi le rọ̀ mọ Ọ: cr Emi nwá oju rere Rẹ, p Pè mi mọ awọn t’o noè --- An’ emi.
mf Má kọja mi, Ẹmi Mimọ, ‘Wọ le laju afọju: Ẹlẹri itoye Jesu, p Sọ̀rọ aṣẹ na si mi --- An’ emi.
mp Mo ti sùn fọnfọn nin’ẹṣẹ, Mo bi Ọ ninu kọja; Aiye ti dè ọkàn mi, jọ, p Tú mi k’o dariji mi --- An’ emi.
cr Ifẹ Ọlọrun ti ki yẹ̀; Ẹjẹ Krist’ iyebiye; ff Ore-ọfẹ alainiwọn; di Gbe gbogbo rẹ̀ ga n’nu mi --- An’ emi.
mp Má kọja mi, dariji mi, Fà mi mọra, Oluwa; ‘Gbà o nf’ibukun f’ ẹlomi, cr Ma’ ṣ’ ai f’ Ibukun fun mi --- An’ emi, An’ emi, p Má ṣ’ ai f’ Ibukun fun mi. Amin.