mp Ibu anu ! O le jẹ Pe anu sì mbẹ fun mi? Ọlọrun le mu surù F’ em’ olori ẹlẹṣẹ? di Mo ti kọ̀ or’-ọfẹ Rẹ̀, Mo bi n’nu lojukoju; Nkò f’ eti si ìpe Rẹ̀; Mo ṣọ ninu l’ainiye.
Mo tàn a ni surù to: Sibẹ o sì da mi si; O nke, --- “Ngo ṣe jọwọ rẹ! Sa gbá ago igbala, p Olugbala mi nduro, O sì nfi ọgbẹ Rẹ hàn; O sì nfi ọgbẹ Rẹ̀ hàn; Mo mọ̀, ifẹ l’ Ọlọrun; pp Jesu nsun, O fẹran mi.
mp Jesu, dahun lat’ oke; Ifẹ k’ ìwa Rẹ gbogbo? ‘Wọ ki y’o dariji mi, Ki nwolẹ li ẹsẹ Rẹ? Bi ‘m’ ba mọ̀ inu Rẹ ‘re, B’ Iwọ ‘ba ṣe alanu, F’ anu dẹti Rẹ silẹ, Dariji, k’o sì gba mi.
F’ oju ìyọ́nu wò mi; Fi wiwò oju pè mi; Mu ọkàn okuta rọ̀; Yipada, rọ̀ mi lọkan, Mu mi ronupiwada; Jẹ ki ngbawẹ f’ ẹṣẹ mi; Ki nsì kanu iṣe mi, cr Ki ngbagbọ, ki nye dẹṣẹ. Amin.