- mp Pada aṣako s’ile rẹ,
Baba rẹ l’o npè ọ;
Ma ṣe alarinkiri mọ,
Nin’ ẹṣẹ at’ òṣi;
pp Pada, pada.
- mp Pada aṣako s’ile rẹ,
Jesu l’o sa npè ọ;
cr Ẹmi pẹlu Ijọ si npè,
Yara sá asalà;
pp Pada, pada.
- mp Pada aṣako s’ile rẹ,
cr Were ni, b’o ba pẹ;
mf Kò si ‘dariji n’iboji,
Ọjọ anu kuru;
pp Pada, pada. Amin.